Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 8:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bẹ́ńjámínì jẹ́ bàbá Bélà àkọ́bí Rẹ̀,Áṣíbélì ọmọkùnrin ni ẹ̀ẹ̀kejì, Áhárá ẹ̀ẹ̀kẹ́ta,

2. Nóhà ẹ̀ẹ̀kẹrin àti Ráfà ẹ̀ẹ̀karùnún.

3. Àwọn ọmọ Bélà jẹ́:Ádárì, Gérà, Ábíhúdì,

4. Ábísúà, Námánì, Áhóà,

5. Gérà, Ṣéfúfánì àti Húrámù.

6. Wọ̀nyí ni àwọn ìran ọmọ Éhúdì, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé tí ó ń gbé ní Gébà tí a sì lé kúrò lọ sí Mánáhátì:

7. Námánì Áhíjà àti Gérà, tí ó lé wọn kúrò ní ìlú, àti tí ó sì jẹ́ baba Úṣà àti Áhíhúdù.

8. A bí àwọn ọmọkùnrin fún Ṣáháráímù ní Móábù lẹ́yìn tí ó ti kọ àwọn ìyàwó Rẹ̀ sílẹ̀, Húṣímù àti Báárà.

9. Nípaṣẹ̀ ìyàwó Rẹ̀ Hódéṣì ó ní Jóbábù ṣíbíà, Méṣà, Málíkámà,

10. Jéúṣì Ṣákíà àti Mírímà. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Rẹ̀, olórí àwọn ìdílé.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 8