32. Hébérì jẹ́ baba Jáfílétì, Ṣómérì àti Hótamì àti ti arábìnrin wọn Ṣúà.
33. Àwọn ọmọ Jáfílétì:Pásákì, Bímíhátì àti Ásífátì.Wọ̀n yí ni àwọn ọmọ Jáfílétì.
34. Àwọn ọmọ Ṣómérì:Áhì, Rógà, Jáhúbà àti Árámù.
35. Àwọn ọmọ arákùnrin Rẹ̀ HélémùṢófà, Ímínà, Ṣélésì àti Ámálì.
36. Àwọn ọmọ Ṣófáhì:Ṣúà, Háníférì, Ṣúálì, Bérì Ímírà.
37. Béṣérì Hódì, Ṣámà, Ṣílísà, Ítíránì àti Bérà.
38. Àwọn ọmọ Jétérì:Jéfúnè Písífà àti Árà.
39. Àwọn ọmọ Úlà:Árà Háníélì àti Résíà.
40. Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ìran ọmọ Áṣérì olórí ìdílé, àwọn okùnrin tí a yàn àwọn ògbóyà jagunjagun àti àwọn adarí tí ó dúró sinsin. Iye àwọn ọkùnrin tí ó setan fún ogun, gẹ́gẹ́ bí à ti se kọ ọ́ lẹ́sẹsẹ nínú ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n.