Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 7:28-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Ilẹ̀ wọn àti ìfìdíkalẹ̀ wọn ni Bétélì àti àwọn ìletò tí ó yíká, Náránì lọ sí ìhà ìlà oòrùn, Géṣérì àti àwọn ìletò Rẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn àti Ṣékémù àti àwọn ìletò Rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Áyáhì àti àwọn ìletò.

29. Lẹ́gbẹ̀ ìpínlẹ̀ ti Mánásè ni Bétí ṣánì, Tánákì, Mógídò àti Dórì lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìletò Rẹ̀. Àwọn ìran ọmọ Jóṣẹ́fù ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé nínú ìlú wọ̀nyí.

30. Àwọn ọmọ Ásérì:Ímíná, Ísúa, Ísúáì àti Béríá. Arábìnrin wọn sì jẹ́ Ṣérà.

31. Àwọn ọmọ Béríá:Hébérì àti Málíkíélì, tí ó jẹ́ baba Bírísáítì.

32. Hébérì jẹ́ baba Jáfílétì, Ṣómérì àti Hótamì àti ti arábìnrin wọn Ṣúà.

33. Àwọn ọmọ Jáfílétì:Pásákì, Bímíhátì àti Ásífátì.Wọ̀n yí ni àwọn ọmọ Jáfílétì.

34. Àwọn ọmọ Ṣómérì:Áhì, Rógà, Jáhúbà àti Árámù.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 7