Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 7:18-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Arábìnrin Rẹ̀. Hámólékétì bí Ṣíhódì, Ábíésérì àti Máhíláhì.

19. Àwọn ọmọ Ṣémídà sì jẹ́:Áhíánì, Ṣékémù, Líkì àti Áníámù.

20. Àwọn ìran ọmọ Éfíráímù:Ṣútéláhì, Bérédì ọmọkùnrin Rẹ̀,Táhátì ọmọ Rẹ̀, Éléádáhì ọmọ Rẹ̀.

21. Táhátì ọmọ Rẹ̀ Ṣábádì ọmọ, Rẹ̀,àti Ṣútéláhì ọmọ Rẹ̀.Éṣérì àti Éléádì ni a pá nípaṣẹ̀ àwọn ọkùnrin bíbí ìbílẹ̀ Gátì Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ fi agbára mú ohun ọ̀sìn wọn

22. Éfíráímù baba wọn sọ̀fọ̀ fún wọn ní ọjọ́ púpọ̀, àwọn ìbátan Rẹ̀ wá láti tù ú nínú.

23. Nígbà náà, ó sùn pẹ̀lú, ìyàwó Rẹ̀, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ ọ́ ní Béríà nítorí òfò ti wà nínú ìdílé náà.

24. Ọmọbìnrin Rẹ̀ sì jẹ́ Ṣárà, ẹni tí ó kọ́ ìsàlẹ̀ àti òkè Bétí-Hórónì àti Úṣénì sérà pẹ̀lú.

25. Réfà jẹ́ ọmọ Rẹ̀, Rẹ́sẹ́fì ọmọ Rẹ̀,Télà ọmọ Rẹ̀, Táhánì ọmọ Rẹ̀,

26. Ládánì ọmọ Rẹ̀ Ámíhúdì ọmọ Rẹ̀,Élíṣámà ọmọ Rẹ̀,

27. Núnì ọmọ Rẹ̀àti Jóṣúà ọmọ Rẹ̀.

28. Ilẹ̀ wọn àti ìfìdíkalẹ̀ wọn ni Bétélì àti àwọn ìletò tí ó yíká, Náránì lọ sí ìhà ìlà oòrùn, Géṣérì àti àwọn ìletò Rẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn àti Ṣékémù àti àwọn ìletò Rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Áyáhì àti àwọn ìletò.

29. Lẹ́gbẹ̀ ìpínlẹ̀ ti Mánásè ni Bétí ṣánì, Tánákì, Mógídò àti Dórì lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìletò Rẹ̀. Àwọn ìran ọmọ Jóṣẹ́fù ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé nínú ìlú wọ̀nyí.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 7