Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 7:10-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ọmọ Jédíáélì:Bílíhánì.Àwọn ọmọ Bílíhánì:Jéúṣì Bẹ́ńjámínì, Éhúdì, Kénánà Ṣétanì, Tárí-Ṣíṣì àti Áhísáhárì.

11. Gbogbo àwọn ọmọ Jédíádì jẹ́ olórí ìdátan Àwọn ẹgbẹ̀rúnmẹ́tadínlógún-ó-lé-nígba akọni ọkùnrin ni ó ti ṣetan láti jáde lọ sí ogun.

12. Àwọn ará Ṣúpímè àti Húpímù jẹ́ àwọn atẹ̀lé fún Írì, àwọn ìran ọmọ Áhérì.

13. Àwọn ọmọ Náfítalì:Jáhíṣíẹ́lì, Gúnì, Jésérì àti Ṣílémù—ọmọ Rẹ̀ nípa Bílíhà.

14. Àwọn ìran ọmọ Mánásè:Ásíríélì jẹ́ ìran ọmọ Rẹ̀ nípa sẹ̀ àlè Rẹ̀ ará Árámù ó bí Mákírì baba Gílíádì.

15. Mákírì sì mú ìyàwó láti àárin àwọn ará Hípímù àti Ṣúpímù. Orúkọ arábìnrin Rẹ̀ a má a jẹ́ Máákà.Orúkọ ìran ọmọ mìíràn a má a jẹ́ Ṣélóféhádì, tí ó ní àwọn ọmọbìnrin nìkan ṣoṣo.

16. Máákà, ìyàwó Mákírì bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ orúkọ Rẹ̀ ní Pérésì. Ó sì pe arákùnrin Rẹ̀ ní Ṣéréṣì, àwọn ọmọ Rẹ̀ sì ní Úlámù àti Rákémù.

17. Ọmọ Úlámù:Bédánì.Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gílíádì ọmọ Mákírì, ọmọ Mánásè.

18. Arábìnrin Rẹ̀. Hámólékétì bí Ṣíhódì, Ábíésérì àti Máhíláhì.

19. Àwọn ọmọ Ṣémídà sì jẹ́:Áhíánì, Ṣékémù, Líkì àti Áníámù.

20. Àwọn ìran ọmọ Éfíráímù:Ṣútéláhì, Bérédì ọmọkùnrin Rẹ̀,Táhátì ọmọ Rẹ̀, Éléádáhì ọmọ Rẹ̀.

21. Táhátì ọmọ Rẹ̀ Ṣábádì ọmọ, Rẹ̀,àti Ṣútéláhì ọmọ Rẹ̀.Éṣérì àti Éléádì ni a pá nípaṣẹ̀ àwọn ọkùnrin bíbí ìbílẹ̀ Gátì Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ fi agbára mú ohun ọ̀sìn wọn

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 7