Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 7:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn ọmọ Ísákárì:Tólà, Púà, Jáṣúbù àti Ṣímírónì, Mẹ́rin ni gbogbo Rẹ̀.

2. Àwọn ọmọ Tólà:Húsì, Réfáíáhì, Jéríélì, Jámáì, Jíbísámù àti Ṣámúẹ́lì Olórí àwọn ìdílé wọn. Ní àkókò ìjọba, Dáfídì, àwọn ìran ọmọ Tólà tò lẹ́sẹsẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin alágbára ní ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlá ó lé ẹgbẹ̀ta (22,600).

3. Àwọn ọmọ, Húṣì:Ísíráhíà.Àwọn ọmọ Ísíráhíà:Míkáélì Ọbádáyà, Jóẹ́lì àti Ísíhíáhì. Gbogbo àwọn máràrùn sì jẹ́ olóyè.

4. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n ní ọkùnrin ẹgbàá mérìndínlógójì tí ó ti ṣe tan fún ogun, nítorí wọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ àti ìyàwó

5. Àwọn ìbátan tí ó jẹ́ alágbára akọni àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ti àwọn ìdílé Ísákárì, bí a ti tò ó lẹ́sẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlàádórin ni gbogbo Rẹ̀.

6. Àwọn ọmọ mẹ́ta Bẹ́ńjámínì:Bélà, Békérì àti Jédíáélì.

7. Àwọn ọmọ Bélà:Éṣíbónì, Húṣì, Ísíélì, Jérómótì àti Írì, àwọn máràrùnún. Awọn ni olórí ilé baba ńlá wọn, akọni alágbára ènìyàn. A sì ka iye wọn nípa ìran wọn sí ẹgbàámọ́kànlá-ó-lé-mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ènìyàn (22,034)

8. Àwọn ọmọ Békérì:Ṣémíráhì, Jóáṣì, Élíásérì, Élíóénáì, omírì, Jeremótù Ábíjà, Ánátótì àti Álémétì Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ọmọ Békérì

9. Ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn tí a kọ lẹ́sẹsẹ jẹ́ ti àwọn olórí ìdílé àti ẹgbẹ̀rún-ní ọ̀nà ogún-ó-lé nígba (20,200) Ọkùnrin alágbára

10. Ọmọ Jédíáélì:Bílíhánì.Àwọn ọmọ Bílíhánì:Jéúṣì Bẹ́ńjámínì, Éhúdì, Kénánà Ṣétanì, Tárí-Ṣíṣì àti Áhísáhárì.

11. Gbogbo àwọn ọmọ Jédíádì jẹ́ olórí ìdátan Àwọn ẹgbẹ̀rúnmẹ́tadínlógún-ó-lé-nígba akọni ọkùnrin ni ó ti ṣetan láti jáde lọ sí ogun.

12. Àwọn ará Ṣúpímè àti Húpímù jẹ́ àwọn atẹ̀lé fún Írì, àwọn ìran ọmọ Áhérì.

13. Àwọn ọmọ Náfítalì:Jáhíṣíẹ́lì, Gúnì, Jésérì àti Ṣílémù—ọmọ Rẹ̀ nípa Bílíhà.

14. Àwọn ìran ọmọ Mánásè:Ásíríélì jẹ́ ìran ọmọ Rẹ̀ nípa sẹ̀ àlè Rẹ̀ ará Árámù ó bí Mákírì baba Gílíádì.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 7