Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 5:9-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Àti níhà àríwá, o tẹ̀dó lọ títí dé àti wọ ihà láti odo Yúfúrátè; nítorí tí ẹran ọ̀sìn wọn pọ̀ si i ní ilẹ̀ Gílíádì.

10. Àti ní ọjọ́ Ṣọ́ọ̀lù, wọ́n bá àwọn ọmọ Hágárì jagun, ẹni tí ó ṣubú nípa ọwọ́ wọn; wọ́n sì ń gbé inú àgọ́ wọn ní gbogbo ilẹ̀ àríwá Gílíádì.

11. Àti àwọn ọmọ Gádì ń gbé ọ̀kánkán wọn, ní ilẹ̀ Básánì títí dé Sálíkà:

12. Jóẹ́lì olórí, Ṣáfámù ìran ọmọ, Jánáì, àti Ṣáfátì ni Básánì,

13. Àti àwọn arákùnrin wọn ti ilẹ̀ àwọn baba wọn ní:Míkáélì, Mésúlímù Ṣébà, Jóráì, Jákánì, Ṣíà àti Hébérì méje.

14. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ábíháílì, ọmọ Húrì, ọmọ Járóà, ọmọ Gílíádì, ọmọ Míkàẹ́lì, ọmọ Jésíháì, ọmọ Jádò ọmọ Búsì.

15. Áhì, ọmọ Ábídélì, ọmọ Gúnì, olórí ilé àwọn baba wọn.

16. Wọ́n sì ń gbé Gílíádì ní Básánì àti nínú àwọn ìlú Rẹ̀, àti nínú gbogbo ìgbéríko Sárónì, ní agbégbé wọn.

17. Gbogbo wọ̀nyí ni a kà nípa ìtàn-ìdílé, ní ọjọ́ Jótamù ọba Júdà, àti ní ọjọ́ Jéróbóámù ọba Ísírẹ́lì.

18. Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àti àwọn ọmọ Gádì, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, nínú àwọn ọkùnrin alágbára tí wọ́n ń gbé aṣà àti idà, tí wọ́n sì ń fi ọrun tafà, tí wọ́n sì mòye ogun, jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ènìyàn o le ẹgbẹ̀rinlélógún dín ogójì, tí ó jáde lọ sí ogún náà.

19. Wọ́n sì bá àwọn ọmọ Hágárì jagun, pẹ̀lú Jétúrì, àti Néfísì àti Nádábù.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 5