Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 5:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àkọ́bí Ísírẹ́lì. (Nítorí òun ni àkọ́bí; ṣùgbọ́n, bí ó ti ṣe pé ó ba ẹní baba Rẹ̀ jẹ́, a fi ogún ìbí Rẹ̀ fún àwọn ọmọ Jóṣẹ́fù ọmọ Ísírẹ́lì: a kì yóò sì ka ìtàn ìdílé náà gẹ́gẹ́ bí ipò ìbí.

2. Nítorí Júdà borí àwọn arákùnrin Rẹ̀, àti lọ́dọ̀ Rẹ̀ ni alásẹ ti ń jáde wá; ṣùgbọ́n ogún ìbí jẹ́ ti Jóṣẹ́fù),

3. àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àkọ́bí Ísírẹ́lì ni:Hánókù àti Pálù, Hésirónì àti Kárímì.

4. Àwọn ọmọ Jóẹ́lì:Ṣémáíà ọmọ Rẹ̀, Gógù ọmọ Rẹ̀,Ṣíméhì ọmọ Rẹ̀.

5. Míkà ọmọ Rẹ̀,Réáíà ọmọ Rẹ̀, Báálì ọmọ Rẹ̀.

6. Béérà ọmọ Rẹ̀, tí Tígílátì-pílínésérì ọba Ásíríà kó ní ìgbékùn lọ: ìjòyè àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ni òun jẹ́.

7. Àti àwọn arákùnrin Rẹ̀ nípa ìdílé wọn, nígbà tí a ń ka ìtàn ìdílé ìran wọn:Jélíélì àti Ṣékáríà ni olórí.

8. Àti Bélà ọmọ Ásásì ọmọ Ṣémà, ọmọ Jóẹ́lì tí ń gbé Áróérì àní títí dé Nébò àti Baaliméónì.

9. Àti níhà àríwá, o tẹ̀dó lọ títí dé àti wọ ihà láti odo Yúfúrátè; nítorí tí ẹran ọ̀sìn wọn pọ̀ si i ní ilẹ̀ Gílíádì.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 5