Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 3:4-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ẹ̀kẹfà ni a bí fún Dáfídì ni Hébúrónì, níbi tí ó ti jẹ ọba fún ọdún méje àti oṣù mẹ́fà.Dáfídì sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́talélọ́gbọ̀n (33).

5. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ wẹ́wẹ́ tí a bí fún un:Ṣámúyà, Ṣóbábù, Náhátì àti Sólómónì. Àwọn mẹ́rin wọ̀nyí sì ni a bí láti ọ̀dọ̀ Bátíṣébà ọmọbìnrin Ámíélì.

6. Íbíhárì sì wà pẹ̀lú, Élíṣúà, Élífélétì,

7. Nógà, Néfégì, Táfíà,

8. Élísámù, Élíádà àti Élífétélì mẹ́sàn án ni wọ́n.

9. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dáfídì yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àlè bí fún un. Támárì sì ni arábìnrin wọn.

10. Ọmọ Sólómónì ni Réhóbóhámù,Ábíjà ọmọ Rẹ̀,Ásà ọmọ Rẹ̀,Jéhósáfátì ọmọ Rẹ̀,

11. Jéhórámù ọmọ Rẹ̀,Áhásáyà ọmọ Rẹ̀,Jóásì ọmọ Rẹ̀,

12. Ámásáyà ọmọ Rẹ̀,Ásáríyà ọmọ Rẹ̀,Jótamù ọmọ Rẹ̀,

13. Áhásì ọmọ Rẹ̀,Hesekíáyà ọmọ Rẹ̀,Mánásè ọmọ Rẹ̀,

14. Ámónì ọmọ Rẹ̀,Jósíà ọmọ Rẹ̀.

15. Àwọn ọmọ Jósíà:Àkọ́bí ọmọ Rẹ̀ ni Jóhánánì,èkejì ọmọ Rẹ̀ ni Jéhóíákímù,ẹ̀kẹta ọmọ Rẹ̀ ni Ṣédékíà,ẹ̀kẹ́rin ọmọ Rẹ̀ ni Ṣálúmù.

16. Àwọn ìran ọmọ Jéhóíákímù:Jékóníà ọmọ Rẹ̀,àti Ṣedékíà.

17. Àwọn ọmọ Jéhóíákímù tí a mú ní ìgbékùn:Ṣálátíélì ọmọ Rẹ̀ ọkùnrin,

18. Málíkírámù, Pédáíyà, Ṣénásárì, Jékámíà, Hósámà àti Nédábíà.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 3