Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 3:4-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ẹ̀kẹfà ni a bí fún Dáfídì ni Hébúrónì, níbi tí ó ti jẹ ọba fún ọdún méje àti oṣù mẹ́fà.Dáfídì sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́talélọ́gbọ̀n (33).

5. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ wẹ́wẹ́ tí a bí fún un:Ṣámúyà, Ṣóbábù, Náhátì àti Sólómónì. Àwọn mẹ́rin wọ̀nyí sì ni a bí láti ọ̀dọ̀ Bátíṣébà ọmọbìnrin Ámíélì.

6. Íbíhárì sì wà pẹ̀lú, Élíṣúà, Élífélétì,

7. Nógà, Néfégì, Táfíà,

8. Élísámù, Élíádà àti Élífétélì mẹ́sàn án ni wọ́n.

9. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dáfídì yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àlè bí fún un. Támárì sì ni arábìnrin wọn.

10. Ọmọ Sólómónì ni Réhóbóhámù,Ábíjà ọmọ Rẹ̀,Ásà ọmọ Rẹ̀,Jéhósáfátì ọmọ Rẹ̀,

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 3