17. Àwọn ọmọ Jéhóíákímù tí a mú ní ìgbékùn:Ṣálátíélì ọmọ Rẹ̀ ọkùnrin,
18. Málíkírámù, Pédáíyà, Ṣénásárì, Jékámíà, Hósámà àti Nédábíà.
19. Àwọn ọmọ Pédáíyà:Ṣérúbábélì àti Ṣíméhì.Àwọn ọmọ Ṣérúbábélì:Mésúlámù àti Hánáníyà,Ṣélómítì ni arábìnrin wọn.
20. Àwọn márùnún mìíràn sì tún wà:Hásúbà, Óhéhì, Bérékíà, Hasádíà àti Jusabi-Hésédì.
21. Àwọn ọmọ Hánáníyà:Pélátíà àti Jeṣáíà, àti àwọn ọmọ Réfáíà, ti Árínánì, ti Ọbadíà àti ti ṣékáníà.
22. Àwọn ọmọ Ṣékáníà:Ṣémáíà àti àwọn ọmọ Rẹ̀:Hátúsì, Ígéálì, Báríà, Néáríà àti Ṣáfátì, mẹ́fà ni gbogbo wọn.