1. Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Dáfídì tí a bí fún un ní Hébírónì:Àkọ́bí sì ni Ámínónì ọmọ Áhínóámù ti Jésírẹ́lì;èkejì sì ni Dáníẹ́lì ọmọ Ábígáílì ará Kárímélì;
2. Ẹ̀kẹta sì ni Ábúsálómù ọmọ Mákà ọmọbìnrin ti Táímáì ọba Gésúrì;ẹ̀kẹrin sì ni Àdóníjà ọmọ Hágítì;
3. Ẹ̀kárùnún ni Ṣéfátíyà ọmọ Ábítalì;àti ẹ̀kẹfà, Ítíréàmù, láti ọ̀dọ̀ ìyàwó Rẹ̀ Égílà.
4. Ẹ̀kẹfà ni a bí fún Dáfídì ni Hébúrónì, níbi tí ó ti jẹ ọba fún ọdún méje àti oṣù mẹ́fà.Dáfídì sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́talélọ́gbọ̀n (33).
5. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ wẹ́wẹ́ tí a bí fún un:Ṣámúyà, Ṣóbábù, Náhátì àti Sólómónì. Àwọn mẹ́rin wọ̀nyí sì ni a bí láti ọ̀dọ̀ Bátíṣébà ọmọbìnrin Ámíélì.