Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 29:3-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Yàtọ̀ fún èyí, nínú ìfọkànsìn mi sí ilé Ọlọ́run mi, èmí fi ìṣúra mi tìkalára mí ti wúrà àti fàdákà fún ilé Ọlọ́run mi, jù gbogbo Rẹ̀ lọ, èmi ti pèṣè fún ilé mímọ́ ti Olúwa yìí:

4. Ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) talẹ́ntì wúrà (wúrà ti ofírì) àti ẹgbẹ̀rin méje tálẹ́ntì fàdákà tí a yọ̀rọ̀ kúrò, fún bíbo àwọn ògiri ilé náà.

5. Fún iṣẹ́ wúrà àti fàdákà náà, àti fún orísìí iṣẹ́ ti ó yẹ ní ṣíṣe nípaṣẹ̀ àwọn tí ó ní òye oríṣíiríṣí iṣẹ́. Níṣinṣìn yìí, ta ni ó ní ìfẹ́ sí yíya ará Rẹ̀ sọ́tọ̀ lónìí sí Olúwa?”

6. Nígbà náà àwọn aṣájú àwọn ìdílé, àwọn ìjòyè àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, àwọn alákòóṣo ẹgbẹgbẹ̀wá àti alákòóṣo ọrọrún àti àwọn oníṣẹ́ tí ó wà ní ìdí iṣẹ́ ọba ní ìfẹ́ sí i.

7. Wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run, ẹgbẹ̀rún márùn-ún talẹ́ntì àti ẹgbẹ̀rin mẹ́wàá (Dáríkì) wúrà, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá talẹ́ntì fàdákà, ẹgbẹ̀rin méjìdínlógún talẹ́ntì òjíá àti ọgọ́rin ẹgbẹ̀rin talẹ́ntì irin.

8. Ẹnikẹ́ni tí ó ní òkúta iyebíye fi wọn sí ilé ìṣúra ilé Ọlọ́run ní ìhámọ́ Jéhíélì ará Géríṣónì.

9. Àwọn ènìyàn láyọ̀ nínú ìṣesí àtọkànwá fi sílẹ̀ àwọn olórí wọn, nítorí tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ọ̀fẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn sí Olúwa. Dáfídì ọba pẹ̀lú yọ̀ gidigidi.

10. Dáfídì yin Olúwa níwájú gbogbo àwọn tí ó péjọ, wí pé,“Ìyìn ni fún Ọ, Olúwa,Ọlọ́run baba a wa Ísírẹ́lì,láé àti láéláé.

11. Tìrẹ Olúwa ni títóbi àti agbára pẹ̀lú ìyìnàti ọlá ńlá àti dídán,nítorí tí gbogbo nǹkan ní ọ̀run àti ayé jẹ́ tìrẹ.Tìrẹ Olúwa ni ìjọba;a gbé ọ ga gẹ́gẹ́ bí orí lórí ohun gbogbo.

12. Ọlá àti ọ̀wọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ;ìwọ ni alákòóso gbogbo nǹkan.Ní ọwọ́ rẹ ni ipá àti agbára wà láti gbéga àtiláti fi agbára fún ohun gbogbo.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 29