Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 29:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà, ọba Dáfídì sọ fún gbogbo àpéjọ pé: “Ọmọ mi Sólomónì, èyí tí Ọlọ́run ti yàn, ṣì kéré ó sì jẹ́ aláìmòye. Iṣẹ́ náà tóbi, nítorí ìkọ́lé bí ti ààfin kì í ṣe fún ènìyàn ṣùgbọ́n fún Olúwa Ọlọ́run.

2. Pẹ̀lu gbogbo ìrànlọ́wọ́ mi èmi ti pèsè fún ilé Ọlọ́run mi wúrà fún iṣẹ́ wúrà, fàdákà fún ti fàdákà, òjíá fún ti òjíá, irin fún ti irin àti igi fún ti igi àti òkúta oníyebíye fún títọ́ Rẹ̀, (túríkúóṣè) òkúta lóríṣíríṣí, àmọ̀ àti oríṣìíríṣìí ẹ̀yà òkúta àti òkuta dáradára kan gbogbo wọ̀nyí ní iye púpọ̀.

3. Yàtọ̀ fún èyí, nínú ìfọkànsìn mi sí ilé Ọlọ́run mi, èmí fi ìṣúra mi tìkalára mí ti wúrà àti fàdákà fún ilé Ọlọ́run mi, jù gbogbo Rẹ̀ lọ, èmi ti pèṣè fún ilé mímọ́ ti Olúwa yìí:

4. Ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) talẹ́ntì wúrà (wúrà ti ofírì) àti ẹgbẹ̀rin méje tálẹ́ntì fàdákà tí a yọ̀rọ̀ kúrò, fún bíbo àwọn ògiri ilé náà.

5. Fún iṣẹ́ wúrà àti fàdákà náà, àti fún orísìí iṣẹ́ ti ó yẹ ní ṣíṣe nípaṣẹ̀ àwọn tí ó ní òye oríṣíiríṣí iṣẹ́. Níṣinṣìn yìí, ta ni ó ní ìfẹ́ sí yíya ará Rẹ̀ sọ́tọ̀ lónìí sí Olúwa?”

6. Nígbà náà àwọn aṣájú àwọn ìdílé, àwọn ìjòyè àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, àwọn alákòóṣo ẹgbẹgbẹ̀wá àti alákòóṣo ọrọrún àti àwọn oníṣẹ́ tí ó wà ní ìdí iṣẹ́ ọba ní ìfẹ́ sí i.

7. Wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run, ẹgbẹ̀rún márùn-ún talẹ́ntì àti ẹgbẹ̀rin mẹ́wàá (Dáríkì) wúrà, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá talẹ́ntì fàdákà, ẹgbẹ̀rin méjìdínlógún talẹ́ntì òjíá àti ọgọ́rin ẹgbẹ̀rin talẹ́ntì irin.

8. Ẹnikẹ́ni tí ó ní òkúta iyebíye fi wọn sí ilé ìṣúra ilé Ọlọ́run ní ìhámọ́ Jéhíélì ará Géríṣónì.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 29