Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 23:5-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ẹgbàájì (4,000) ni kí ó jẹ́ olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà àti ẹgbàajì (4,000) ni kí o sì jẹ́ ẹni ti yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin, mo ti se èyí fún ìdí pàtàkì yìí.

6. Dáfídì sì pín àwọn ọmọ Léfì sí ẹgbẹgbẹ́ láàrin àwọn ọmọ Léfì Gérísónì, Kóhátì àti Mérárì.

7. Àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Gérísónì:Ládánì àti Ṣíméhì.

8. Àwọn ọmọ LádánìJéhíélì ẹni àkọ́kọ́, Ṣétanì àti Jóẹ́lì ẹ̀kẹ́ta ní gbogbo wọn.

9. Àwọn ọmọ Ṣímè:Ṣélómótì, Hásíélì àti Háránì mẹ́ta ní gbogbo wọn.Àwọn wọ̀nyí sì ni olórí àwọn ìdílé Ládánì.

10. Àti ọmọ Ṣímélì:Jáhátì, Ṣísà, Jéúsì àti Béríà.Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ṣíméhì mẹ́rin ni gbogbo wọn.

11. Jáhátì sì ni alákọ́kọ́ Ṣísà sì ni ẹlẹ́kejì, ṣùgbọ́n Jéúsì àti Béríà kò ní àwọn ọmọ púpọ̀; Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ka ara wọn sí ìdílé kan pẹ̀lú ìfilé lọ́wọ́ kan.

12. Àwọn ọmọ kóhátì:Ámírámù, Ísárì, Hébúrónì àti Usíélì mẹ́rin ni gbogbo wọn.

13. Àwọn ọmọ Ámírámù.Árónì àti Móṣè.A sì ya Árónì sọ́tọ̀ òun àti àwọn ọmọ Rẹ̀ títí láéláé, láti kọjú sí ohun mímọ́ jùlọ, láti fi rúbọ sísun níwájú Olúwa, láti máa ṣe òjísẹ́ níwájú Rẹ̀ àti láti kéde ìbùkún ní orúkọ Rẹ̀ títí láéláé.

14. Àwọn ọmọ Mósè ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí apákan ẹ̀yà Léfì.

15. Àwọn ọmọ Mósè;Gérísónì àti Élíásérì.

16. Àwọn ọmọ GérísónìṢúbáélì sì ni alákọ́kọ́.

17. Àwọn ọmọ Élíásérì:Réhábíà sì ni ẹni àkọ́kọ́.Élíásérì kò sì tún ní ọmọ mìíràn, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Réhábíà wọ́n sì pọ̀ níye.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 23