Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 23:12-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Àwọn ọmọ kóhátì:Ámírámù, Ísárì, Hébúrónì àti Usíélì mẹ́rin ni gbogbo wọn.

13. Àwọn ọmọ Ámírámù.Árónì àti Móṣè.A sì ya Árónì sọ́tọ̀ òun àti àwọn ọmọ Rẹ̀ títí láéláé, láti kọjú sí ohun mímọ́ jùlọ, láti fi rúbọ sísun níwájú Olúwa, láti máa ṣe òjísẹ́ níwájú Rẹ̀ àti láti kéde ìbùkún ní orúkọ Rẹ̀ títí láéláé.

14. Àwọn ọmọ Mósè ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí apákan ẹ̀yà Léfì.

15. Àwọn ọmọ Mósè;Gérísónì àti Élíásérì.

16. Àwọn ọmọ GérísónìṢúbáélì sì ni alákọ́kọ́.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 23