Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 23:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Dáfídì sì dàgbà tí ó sì kún fún ọjọ́, ó sì fi Sólómónì ọmọ Rẹ̀ jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì.

2. Ó sì kó gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ, àti gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì.

3. Àwọn ọmọ Lefì lati ọgbọ̀n ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n kà àpapọ̀ iye àwọn ọkùnrin wọn sì jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlógún (38,000)

4. Dáfídì sì wí pe, Níti èyí, ẹgbàáméjìlá (24,000) ni kí wọn jẹ́ alábojútó iṣẹ́ ilé fún Olúwa àti ẹgbàáta (6,000) ni kí ó ṣe olórí àti onídàájọ́.

5. Ẹgbàájì (4,000) ni kí ó jẹ́ olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà àti ẹgbàajì (4,000) ni kí o sì jẹ́ ẹni ti yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin, mo ti se èyí fún ìdí pàtàkì yìí.

6. Dáfídì sì pín àwọn ọmọ Léfì sí ẹgbẹgbẹ́ láàrin àwọn ọmọ Léfì Gérísónì, Kóhátì àti Mérárì.

7. Àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Gérísónì:Ládánì àti Ṣíméhì.

8. Àwọn ọmọ LádánìJéhíélì ẹni àkọ́kọ́, Ṣétanì àti Jóẹ́lì ẹ̀kẹ́ta ní gbogbo wọn.

9. Àwọn ọmọ Ṣímè:Ṣélómótì, Hásíélì àti Háránì mẹ́ta ní gbogbo wọn.Àwọn wọ̀nyí sì ni olórí àwọn ìdílé Ládánì.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 23