Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 21:27-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Nígbà náà Olúwa sọ̀rọ̀ sí ańgẹ́lì, ó sì gbé idà padà bọ̀ sínú àkọ̀ Rẹ̀.

28. Ní àkókò náà nígbà tí Dáfídì sì rí wí pé Olúwa ti dá a lóhùn lórí ilẹ̀ ìpakà ti Órínán ará Jébúsì, ó sì rú ẹbọ ọrẹ sísun níbẹ̀.

29. Àgọ́ Olúwa tí Mósè ti ṣe ní ihà, àti pẹpẹ ẹbọ ọrẹ ṣíṣun wà lórí ibi gíga ní Gíbíónì ní àkókò náà.

30. Ṣùgbọ́n Dáfídì kò lè lọ ṣíwájú Rẹ̀ láti béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí tí ó bẹ̀rù nípa idà ọwọ́ ańgẹ́lì Olúwa.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 21