Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 21:25-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì san ẹgbẹ̀ta ṣékélì wúrà fún Órínánì nípa ìwọ̀n fún ibẹ̀ náà.

26. Dáfídì sì tẹ́ pẹpẹ fún Olúwa níbẹ̀ ó sì ní ẹbọ ọrẹ sísun àti ẹbọ ọrẹ àlàáfíà. Ó sì pe orúkọ Olúwa, Olúwa sì da lóhùn pẹ̀lú iná láti òkè ọ̀run lórí pẹpẹ fún ẹbọ ọrẹ ṣíṣun.

27. Nígbà náà Olúwa sọ̀rọ̀ sí ańgẹ́lì, ó sì gbé idà padà bọ̀ sínú àkọ̀ Rẹ̀.

28. Ní àkókò náà nígbà tí Dáfídì sì rí wí pé Olúwa ti dá a lóhùn lórí ilẹ̀ ìpakà ti Órínán ará Jébúsì, ó sì rú ẹbọ ọrẹ sísun níbẹ̀.

29. Àgọ́ Olúwa tí Mósè ti ṣe ní ihà, àti pẹpẹ ẹbọ ọrẹ ṣíṣun wà lórí ibi gíga ní Gíbíónì ní àkókò náà.

30. Ṣùgbọ́n Dáfídì kò lè lọ ṣíwájú Rẹ̀ láti béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí tí ó bẹ̀rù nípa idà ọwọ́ ańgẹ́lì Olúwa.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 21