Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 21:14-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa rán àjàkálẹ̀-àrùn lórí Ísírẹ́lì, ẹgbàá márùndínlógójì (70,000) ènìyàn Ísírẹ́lì sì kú.

15. Ọlọ́run sì rán ańgẹ́lì láti pa Jérúsálẹ́mù run. Ṣùgbọ́n bí áńgẹ́lì ti ń ṣe èyí, Olúwa sì ríi. Ó sì káàánú nítorí ibi báà, ó sì wí fún áńgẹ́lì tí ó pa àwọn ènìyàn náà run pé, “Ó ti tó! Dá ọwọ́ rẹ dúró.” Ańgẹ́lì Olúwa náà sì dúró níbi ilẹ̀ ìpakà Áráúnà ará Jébúsì.

16. Dáfídì sì wòkè ó sì rí áńgẹ́lì Olúwa dúró láàrin ọ̀run àti ayé pẹ̀lú idà fífàyọ ní ọwọ́ Rẹ̀ tí ó sì nàá sórí Jérúsálẹ́mù. Nígbà náà Dáfídì àti àwọn àgbààgbà, sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da ojú wọn bolẹ̀.

17. Dáfídì sì wí fún Ọlọ́run pé, “Èmi ha kọ́ ni mo paláṣẹ àti ka àwọn jagunjagun ènìyàn? Èmi ni ẹni náà tí ó dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe ohun tí kò dára, wọ̀nyí ni àgùntàn. Kí ni wọ́n ṣe? Olúwa Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára mi àti àwọn ìdíle mi, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí àjàkálẹ̀-àrùn yìí kí ó dúró lóri àwọn ènìyàn rẹ.”

18. Nígbà náà ańgẹ́lì Olúwa náà pàṣẹ̀ fún Gádì láti sọ fún Dáfídì láti lọ sókè kí ó sì kọ́ pẹpẹ fún Olúwa lórí ilẹ̀ ìpakà ti Órínánì ará Jébúsì.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 21