Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 17:14-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Èmi yóò gbé e ka orí ilé mi àti ìjọba mi títí láé; ìtẹ́ Rẹ̀ ni a ó fi ìdí Rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.’ ”

15. Nátanì ròyìn fún Dáfídì gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ ti Ìfihàn yí.

16. Nígbà náà, ọba Dáfídì wọlé lọ, ó sì jòkó níwájú Olúwa ó sì wí pé:“Ta ni èmi, Olúwa Ọlọ́run, àti ki ni ìdílé mi, tí ìwọ mú mi dé ibí?

17. Pẹ̀lú bí ẹni pé èyí kò tó lojú rẹ, Ọlọ́run. Ìwọ ti sọ̀rọ̀ nipa ọjọ́ iwáju ilé ìránṣẹ́ rẹ. Ìwọ ti wò mí bí ẹni pé èmi ni ẹni gbígbéga jù láàárin àwọn ọkùnrin Olúwa Ọlọ́run.

18. “Kí ni ohun tí Dáfídì tún lè sọ nítorí ọlá tí o bù fún ìránṣẹ́ rẹ? Nítorí tí ìwọ mọ ìransẹ́ rẹ,

19. Olúwa. Nítorí ti ìránṣẹ́ rẹ àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ rẹ, ìwọ ti ṣe ohun ńlá yìí àti láti fi gbogbo ìleri ńlá yìí hàn.

20. “Kò sí ẹnìkan bí ì rẹ, kò sì sí Ọlọ́run kan àfi ìwọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí à ti gbọ́ pẹ̀lú etí ara wa.

21. Pẹ̀lú ta ni ó dà bí àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì-orílẹ̀ èdè kan ní ayé, tí Ọlọ́run jáde lọ láti ra àwọn ènìyàn kan padà fún ara Rẹ̀, àti láti lè ṣe orúkọ fún ara à rẹ, àti lati ṣe ohun ńlá àti ọwọ́ ìyanu nípa lílé àwọn orílẹ̀ èdè kúrò níwáju àwọn ènìyàn Rẹ̀, ẹni tí ó gbà là láti Éjíbítì?

22. Ìwọ se àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì ní tìrẹ láéláé ìwọ Olúwa sì ti di Ọlọ́run wọn.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 17