Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 16:25-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Nítorí títóbi ni Olúwa òun sì ni ìyìn yẹ Jùlọ;òun ni kí a bẹ̀rù ju gbogbo àwon Ọlọ́run lọ.

26. Nítorí gbogbo àwọn Ọlọ́run orílẹ̀ èdè jẹ́ àwọn òrìsà,ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run.

27. Dídán àti ọlá-ńlá ni ó wà ní wájú Rẹ̀;agbára àti ayọ̀ ni ó wà ní ibi ibùgbé Rẹ̀.

28. Fifún Olúwa, ẹ̀yin ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè,ẹ fi ògo àti ipá fún Olúwa,

29. fún Olúwa ní ìyìn nítorí orúkọ Rẹ̀.Gbé ọrẹ kí ẹ sì wá ṣíwájú Rẹ̀;Sìn Olúwa nínú inú dídùn ìwà mímọ́ Rẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 16