Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 16:17-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ó ṣe ìdánilójú u Rẹ̀ fún Jákọ́bù gẹ́gẹ́ bí òfin,sí Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú láéláé.

18. “Sí ọ, ni Èmi yóò fún ní ilẹ̀ Kénánì.Gẹ́gẹ́ bí àyè tí ìwọ yóò jogún.”

19. Nígbà tí wọn kéré ní iye,wọ́n kéré gidigidi, wọ́n sì jẹ́ àlejò níbẹ̀,

20. wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀ èdè sí orílẹ̀-èdèláti ìjọba kan sí èkejì.

21. Kò gba ọkùnrin kankan láyè láti pọ́n wọn lójú;nítorí ti wọn, ó bá àwọn ọba wí.

22. “Má ṣe fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi;Má ṣe pa àwọn wòlíì mi lára.”

23. Kọrin sí Olúwa gbogbo ayé;ẹ máa fi ìgbàlà Rẹ̀ hàn láti ọjọ́ dé ọjọ́.

24. Kéde ìgbàlà à Rẹ̀ láàárin àwọn orílẹ̀-èdè,ohun ìyàlẹ́nu tí ó se láàrin gbogbo ènìyàn.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 16