Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 16:15-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ó ránti májẹ̀mú rẹ́ títí láé,ọ̀rọ̀ tí Ó pa láṣẹ fún ẹgbẹ̀rún ìran,

16. Májẹ̀mu tí ó dá pẹ̀lú Ábúráhámù,ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Ísákì.

17. Ó ṣe ìdánilójú u Rẹ̀ fún Jákọ́bù gẹ́gẹ́ bí òfin,sí Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú láéláé.

18. “Sí ọ, ni Èmi yóò fún ní ilẹ̀ Kénánì.Gẹ́gẹ́ bí àyè tí ìwọ yóò jogún.”

19. Nígbà tí wọn kéré ní iye,wọ́n kéré gidigidi, wọ́n sì jẹ́ àlejò níbẹ̀,

20. wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀ èdè sí orílẹ̀-èdèláti ìjọba kan sí èkejì.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 16