9. Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ pakà ti Kídónì, Úsà na ọwọ́ Rẹ̀ síta láti di àpótì ẹ̀rí Olúwa mú, nítorí màlúù kọ̀ṣẹ̀.
10. Ìbínú Olúwa, sì ru sí Úsà, ó sì lùú bolẹ̀ nítorí o ti fi ọwọ́ Rẹ̀ lórí Àpótí ẹ̀rí. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run.
11. Nígbà náà Dáfídì sì bínú nítorí ìbínú Olúwa ké jáde lórí Úsá, àti títí di òní, wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní péresì-Ùsà.
12. Dáfídì sì bẹ̀rù Ọlọ́run ní ọjọ́ náà, ó sì bèèrè pé, Báwo ni èmi náà ó ṣe gbé àpótí ẹ̀rí Olórun sí ọ̀dọ̀ mi?
13. Kò gbé àpótí ẹ̀rí náà wá sí ọ̀dọ̀ ará Rẹ̀ ní ìlú ti Dáfídì dípò èyí, ó sì gbé e sí ẹ̀gbé, sí ilé Obedi-Édómù ará Gítì.
14. Àpótí ẹ̀rí Olúwa sì wà lọ́dọ̀ àwon ará ilé Obedi-Édómù ní ilé Rẹ̀ fún oṣù mẹ́ta, Olúwa sì bùkún agbo ilé àti gbogbo ohun tí ó ní.