Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 13:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Dáfídì sì gbérò pẹ̀lú olúkúlùkù àwọn ìjòyè Rẹ̀, àwọn aláṣẹ ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn aláṣẹ́ ọgọ́rùn ún

2. Ó sì wí fún gbogbo àwọn ìjọ Ísírẹ́lì pé Tí ó bá dára lójú yín àti tí ó bá ṣe jẹ́ àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa, jẹ́ kí a ránṣẹ́ sí ọ̀nà jínjìn àti gbígbòòrò sí àwọn arákùnrin wa tó kù ní gbogbo àwọn agbègbè ìlú Ísírẹ́lì àti pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn nínú ìlú wọn àti pápá oko tútù, láti wá kó ara wọn jọpọ̀ sọ́dọ̀ wa.

3. Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa padà sọ́dọ̀ wa, nítorí wí pé àwa kò ṣe ìwádìí nípa Rẹ̀ ní àsìkò ìjọba Ṣọ́ọ̀lù

4. Gbogbo ìjọ náà sì gbà láti ṣe èyí nítorí ó dàbí wí pé ó tọ lójú gbogbo àwọn ènìyàn.

5. Nígbà náà ni Dáfídì pe gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ, láti ọ̀dọ̀ Ṣíhórì ní Éjíbítì lọ sí Lébò ní ọ̀nà à bá wọ Hámátì, láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run padà láti Kiriati Jéárímù.

6. Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú Rẹ̀ lọ sí Báláhì ti Júdà (Kiriati-Jéárímù) láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Olúwa tí a fi orúkọ Rẹ̀ pè, tí ó jókòó láàrin kérúbù-gòkè wá.

7. Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run láti ilé Ábínádábù lórí kẹ̀kẹ́ túntún, Usà àti Áhíò ń sọ́ ọ.

8. Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú gbogbo agbára wọn níwájú Ọlọ́run, pẹ̀lú orin àti pẹ̀lú ohun èlò orin olóhùn gooro, písátérù, tíńbálì, síńbálì àti ìpè.

9. Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ pakà ti Kídónì, Úsà na ọwọ́ Rẹ̀ síta láti di àpótì ẹ̀rí Olúwa mú, nítorí màlúù kọ̀ṣẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 13