Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 11:22-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Bẹ́náyà ọmọ Jéhóíádà ó sì jẹ́ akọni oníjà láti Kábísélì, ẹni tí ó se iṣẹ́ agbára ńlá. Ó sì pa méjì nínú àwọn ọkùnrin tí ó dára jù, ó sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí inú ihò lákókò sno ó sì pa kìnnìún kan

23. Ó sì pa ara Éjíbítì ẹni tí ó ga ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ méje àti ààbọ̀ ṣùgbọ́n àwọn ará Éjíbítì wọn ní ọ̀kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdubú igi àwunṣọ àti ọ̀pá ní ọwọ́ Rẹ̀, Bénáyà sọ̀kalẹ̀ lórí Rẹ̀ pẹ̀lú kùmọ̀. Ó sì gba ọ̀kọ̀ náà láti ọwọ́ ará Éjíbítì ó sì pa á pẹ̀lú ọ̀kọ̀ Rẹ̀.

24. Nǹkan wọ̀nyí sì ní ìwà akin. Bénáìá ọmọ Jéhóíádà; ohun náà pẹ̀lú sì di ọlálá gẹ́gẹ́ bí àwọn akọni ọkùnrin mẹ́ta.

25. Ó sì ní ọlá púpọ̀ ju àwọn ọgbọ̀n (30) lọ, ṣùgbọ́n a kò káà láàrin àwọn mẹ́tẹ̀ta. Dáfídì sì fi sí ìkáwọ́ àwọn ẹ̀sọ́.

26. Àwọn akọni ọkùnrin náà nìyí:Ásáhélì arákùnrin Jóábù,Élíhánánì ọmọ Dódò láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,

27. Ṣámótù ará Hárórì,Hélésì ará Pélónì

28. Írà ọmọ Íkéṣì láti Tékóà,Ábíésérì láti Ánátótì,

29. Ṣíbékíà ará Húṣátì,láti ará Áhóhì

30. Máháráì ará Nétófà,Hélédì ọmọ Báánà ará Nétófà,

31. Ítaì ọmọ Ríbáì láti Gíbéà ní Bẹ́ńjámínì,Bẹ́náyà ará Pírátónì,

32. Húráì láti odò Gáṣì,Ábíélì ará Áríbátì,

33. Ásímáfétì ará BáhárúmùÉlíábà ará Ṣáíbónì

34. Àwọn ọmọ Háṣémù ará GísónìJónátanì ọmọ ṣágè ará Hárárì.

35. Áhíámù ọmọ sákárì ará Hárárì,Élífálì ọmọ Úrì

36. Héférì ará Mékérátì,Áhíjà ará Pélónì,

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 11