Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 11:21-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Ó sì gba ìlọ́po ọlá lórí àwọn mẹ́tẹ̀ta ó sì di olórí wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ka kún ara wọn.

22. Bẹ́náyà ọmọ Jéhóíádà ó sì jẹ́ akọni oníjà láti Kábísélì, ẹni tí ó se iṣẹ́ agbára ńlá. Ó sì pa méjì nínú àwọn ọkùnrin tí ó dára jù, ó sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí inú ihò lákókò sno ó sì pa kìnnìún kan

23. Ó sì pa ara Éjíbítì ẹni tí ó ga ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ méje àti ààbọ̀ ṣùgbọ́n àwọn ará Éjíbítì wọn ní ọ̀kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdubú igi àwunṣọ àti ọ̀pá ní ọwọ́ Rẹ̀, Bénáyà sọ̀kalẹ̀ lórí Rẹ̀ pẹ̀lú kùmọ̀. Ó sì gba ọ̀kọ̀ náà láti ọwọ́ ará Éjíbítì ó sì pa á pẹ̀lú ọ̀kọ̀ Rẹ̀.

24. Nǹkan wọ̀nyí sì ní ìwà akin. Bénáìá ọmọ Jéhóíádà; ohun náà pẹ̀lú sì di ọlálá gẹ́gẹ́ bí àwọn akọni ọkùnrin mẹ́ta.

25. Ó sì ní ọlá púpọ̀ ju àwọn ọgbọ̀n (30) lọ, ṣùgbọ́n a kò káà láàrin àwọn mẹ́tẹ̀ta. Dáfídì sì fi sí ìkáwọ́ àwọn ẹ̀sọ́.

26. Àwọn akọni ọkùnrin náà nìyí:Ásáhélì arákùnrin Jóábù,Élíhánánì ọmọ Dódò láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,

27. Ṣámótù ará Hárórì,Hélésì ará Pélónì

28. Írà ọmọ Íkéṣì láti Tékóà,Ábíésérì láti Ánátótì,

29. Ṣíbékíà ará Húṣátì,láti ará Áhóhì

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 11