12. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, iṣẹ ti emi nṣe li on na yio ṣe pẹlu; iṣẹ ti o tobi jù wọnyi lọ ni yio si ṣe; nitoriti emi nlọ sọdọ Baba.
13. Ohunkohun ti ẹnyin ba si bère li orukọ mi, on na li emi ó ṣe, ki a le yìn Baba logo ninu Ọmọ.
14. Bi ẹnyin ba bère ohunkohun li orukọ mi, emi ó ṣe e.
15. Bi ẹnyin ba fẹran mi, ẹ ó pa ofin mi mọ́.
16. Emi ó si bère lọwọ Baba, on ó si fun nyin li Olutunu miran, ki o le mã ba nyin gbé titi lailai,
17. Ani Ẹmí otitọ nì; ẹniti araiye kò le gbà, nitoriti kò ri i, bẹ̃ni kò si mọ̀ ọ: ṣugbọn ẹnyin mọ̀ ọ; nitoriti o mba nyin gbe, yio si wà ninu nyin.