Ki si iṣe pe kìki iṣẹ-ọnà wa yi li o wà li ewu ati di asan; ṣugbọn ile Diana oriṣa nla yio si di gigàn pẹlu, ati gbogbo ọla nla rẹ̀ yio si run, ẹniti gbogbo Asia ati gbogbo aiye mbọ.