23. Wọnyi pẹlu ni ọ̀rọ awọn ọlọgbọ́n. Kò dara lati ṣe ojuṣãju ni idajọ.
24. Ẹniti o ba wi fun enia buburu pe, olododo ni iwọ; on ni awọn enia yio bú, awọn orilẹ-ède yio si korira rẹ̀.
25. Ṣugbọn awọn ti o ba a wi ni yio ni inu-didùn, ibukún rere yio si bọ̀ sori wọn.
26. Yio dabi ẹniti o ṣe ifẹnukonu: ẹniti o ba ṣe idahùn rere.
27. Mura iṣẹ rẹ silẹ lode, ki o si fi itara tulẹ li oko rẹ; nikẹhin eyi, ki o si kọ́ ile rẹ.
28. Máṣe ẹlẹri si ẹnikeji rẹ lainidi: ki iwọ ki o má si ṣe fi ète rẹ ṣẹ̀tan.
29. Máṣe wipe, bẹ̃li emi o ṣe si i, gẹgẹ bi o ti ṣe si mi: emi o san a fun ọkunrin na gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀.
30. Mo kọja lọ li oko ọlẹ, ati lẹba ọgbà-ajara ẹniti oye kù fun:
31. Si kiyesi i, ẹgún kún bo gbogbo rẹ̀, igbó si bo oju rẹ̀, iganna okuta rẹ̀ si wo lulẹ.
32. Nigbana ni mo ri, mo si fi ọkàn mi si i gidigidi: mo wò o, mo si gbà ẹkọ́.
33. Orun diẹ si i, õgbe diẹ, ikawọkòpọ lati sùn diẹ.
34. Bẹ̃li òṣi rẹ yio de bi ẹniti nrìn; ati aini rẹ bi ọkunrin ti o hamọra ogun.