9. Ẹniti o lọra pẹlu ni iṣẹ rẹ̀, arakunrin jẹguduragudu enia ni.
10. Orukọ Oluwa, ile-iṣọ agbara ni: Olododo sá wọ inu rẹ̀, o si là.
11. Ọrọ̀ ọlọrọ̀ ni ilu-agbara rẹ̀, o si dabi odi giga li oju ara rẹ̀.
12. Ṣaju iparun, aiya enia a ṣe agidi, ṣaju ọlá si ni irẹlẹ.
13. Ẹniti o ba dahùn ọ̀rọ ki o to gbọ́, wère ati itiju ni fun u.
14. Ọkàn enia yio faiyàrán ailera rẹ̀; ṣugbọn ọkàn ti o rẹ̀wẹsi, tani yio gbà a?
15. Aiya amoye ni ìmọ; eti ọlọgbọ́n a si ma ṣe afẹri ìmọ.
16. Ọrẹ enia a ma fi àye fun u, a si mu u wá siwaju awọn enia nla.
17. Ẹnikini ninu ẹjọ rẹ̀ a dabi ẹnipe o jare, ṣugbọn ẹnikeji rẹ̀ a wá, a si hudi rẹ̀ silẹ.
18. Keké mu ìja pari, a si làja lãrin awọn alagbara.
19. Arakunrin ti a ṣẹ̀ si, o ṣoro jù ilu olodi lọ: ìja wọn si dabi ọpá idabu ãfin.
20. Ọ̀rọ ẹnu enia ni yio mu inu rẹ̀ tutu: ibisi ẹnu rẹ̀ li a o si fi tù u ninu.
21. Ikú ati ìye mbẹ ni ipa ahọn: awọn ẹniti o ba si nlò o yio jẹ ère rẹ̀.