5. Kò dara lati ṣe ojuṣãju enia-buburu, lati bì olododo ṣubu ni idajọ.
6. Ete aṣiwère bọ sinu ìja, ẹnu rẹ̀ a si ma pè ìna wá.
7. Ẹnu aṣiwère ni iparun rẹ̀, ète rẹ̀ si ni ikẹkùn ọkàn rẹ̀.
8. Ọ̀rọ olofofo dabi adidùn, nwọn a si wọ isalẹ inu lọ.
9. Ẹniti o lọra pẹlu ni iṣẹ rẹ̀, arakunrin jẹguduragudu enia ni.
10. Orukọ Oluwa, ile-iṣọ agbara ni: Olododo sá wọ inu rẹ̀, o si là.
11. Ọrọ̀ ọlọrọ̀ ni ilu-agbara rẹ̀, o si dabi odi giga li oju ara rẹ̀.
12. Ṣaju iparun, aiya enia a ṣe agidi, ṣaju ọlá si ni irẹlẹ.
13. Ẹniti o ba dahùn ọ̀rọ ki o to gbọ́, wère ati itiju ni fun u.
14. Ọkàn enia yio faiyàrán ailera rẹ̀; ṣugbọn ọkàn ti o rẹ̀wẹsi, tani yio gbà a?
15. Aiya amoye ni ìmọ; eti ọlọgbọ́n a si ma ṣe afẹri ìmọ.