17. Ẹniti o ba pa ẹkọ́ mọ́, o wà ni ipa-ọ̀na ìye; ṣugbọn ẹniti o ba kọ̀ ibawi o ṣìna.
18. Ẹniti o ba pa ikorira mọ́ li ète eke, ati ẹniti o ba ngba ọ̀rọ-ẹ̀hin, aṣiwere ni.
19. Ninu ọ̀rọ pipọ, a kò le ifẹ ẹ̀ṣẹ kù: ṣugbọn ẹniti o fi ète mọ ète li o gbọ́n.
20. Ahọn olõtọ dabi ãyo fadaka: aiya enia buburu kò ni iye lori.
21. Ete olododo mbọ́ ọ̀pọlọpọ enia: ṣugbọn awọn aṣiwere yio kú li ailọgbọ́n.
22. Ibukún Oluwa ni imu ni ilà, kì isi ifi lãla pẹlu rẹ̀.
23. Bi ẹrín ni fun aṣiwere lati hu ìwa-ika: ṣugbọn ọlọgbọ́n li ẹni oye.
24. Ibẹ̀ru enia buburu mbọwá ba a: ṣugbọn ifẹ olododo li a o fi fun u.
25. Bi ìji ti ijà rekọja: bẹ̃li enia buburu kì yio si mọ: ṣugbọn olododo ni ipilẹ ainipẹkun.
26. Bi ọti kikan si ehin, ati bi ẽfin si oju, bẹ̃li ọlẹ si ẹniti o rán a ni iṣẹ.