1. AWỌN ọrun nsọ̀rọ ogo Ọlọrun; ati ofurufu nfi iṣẹ ọwọ rẹ̀ han.
2. Ọjọ de ọjọ nfọhùn, ati oru de oru nfi ìmọ hàn.
3. Kò si ohùn kan tabi ède kan, nibiti a kò gbọ́ iró wọn.
4. Iró wọn la gbogbo aiye ja, ati ọ̀rọ wọn de opin aiye: ninu wọn li o gbe pagọ fun õrun.
5. Ti o dabi ọkọ iyawo ti njade ti iyẹwu rẹ̀ wá, ti o si yọ̀ bi ọkunrin alagbara lati sure ije.