13. Nwọn kò pẹ igbagbe iṣẹ rẹ̀: nwọn kò si duro de imọ̀ rẹ̀.
14. Nwọn si ṣe ifẹkufẹ li aginju, nwọn si dan Ọlọrun wò ninu aṣálẹ̀.
15. O si fi ifẹ wọn fun wọn; ṣugbọn o rán rirù si ọkàn wọn.
16. Nwọn ṣe ilara Mose pẹlu ni ibudo, ati Aaroni, ẹni-mimọ́ Oluwa.
17. Ilẹ là, o si gbé Datani mì, o si bò ẹgbẹ́ Abiramu mọlẹ.
18. Iná si ràn li ẹgbẹ́ wọn; ọwọ́ iná na jó awọn enia buburu.
19. Nwọn ṣe ẹgbọrọ malu ni Horebu, nwọn si foribalẹ fun ere didà.