Mose si sọ fun awọn enia na pe, Ki ninu nyin ki o hamọra ogun, ki nwọn ki o si tọ̀ awọn ara Midiani lọ, ki nwọn ki o si gbẹsan OLUWA lara Midiani.