Ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i patapata lati ọjọ́ dé ọjọ́; njẹ o fi mu gbogbo ẹjẹ́ rẹ̀ duro, tabi gbogbo ìde rẹ̀ ti mbẹ lara rẹ̀; o mu wọn duro, nitoriti o pa ẹnu rẹ̀ mọ si i li ọjọ́ na ti o gbọ́.