51. Bi ọdún rẹ̀ ba kù pupọ̀ sibẹ̀, gẹgẹ bi iye wọn ni ki o si san owo ìrasilẹ rẹ̀ pada ninu owo ti a fi rà a.
52. Bi o ba si ṣepe kìki ọdún diẹ li o kù titi di ọdún jubeli, njẹ ki o ba a ṣìro, gẹgẹ bi iye ọdún rẹ̀ ni ki o san owo ìrasilẹ rẹ̀ pada.
53. Bi alagbaṣe ọdọdún ni ki o ma ba a gbé: ki on ki o máṣe fi irorò sìn i li oju rẹ.
54. Bi a kò ba si fi wọnyi rà a silẹ, njẹ ki o jade lọ li ọdún jubeli, ati on, ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀.
55. Nitoripe iranṣẹ mi li awọn ọmọ Israeli iṣe; iranṣẹ mi ni nwọn ti mo mú lati ilẹ Egipti jade wá: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.