5. Tali o jọ̃ kẹtẹkẹtẹ-oko lọwọ, tabi tali o tú ide kẹtẹkẹtẹ igbẹ́?
6. Eyi ti mo fi aginju ṣe ile fun, ati ilẹ iyọ̀ ni ibugbe rẹ̀.
7. O rẹrin si ariwo ilu, bẹ̃ni on kò si gbọ́ igbe darandaran.
8. Ori àtòle oke-nla ni ibujẹ oko rẹ̀, on a si ma wá ewe tutu gbogbo ri.
9. Agbanrere ha jẹ sìn ọ bi, tabi o jẹ duro ni ibujẹ ẹran rẹ?
10. Iwọ le ifi kátà dè agbanrere ninu aporo, tabi o jẹ ma fà itulẹ ninu aporo oko tọ̀ ọ lẹhin?
11. Iwọ o gbẹkẹlẹ e, nitori agbara rẹ̀ pọ̀, iwọ o si fi iṣẹ rẹ le e li ọwọ?
12. Iwọ le igbẹkẹle e pe, yio mu eso oko rẹ wá sile; pe, yio si ko o jọ sinu àka rẹ̀?
13. Iyẹ abo-ogongo nfi ayọ̀ fì, iyẹ ati ihuhu rẹ̀ daradara ni bi?
14. Kò ri bẹ̃? o fi ẹyin rẹ̀ silẹ-yilẹ, a si mu wọn gbona ninu ekuru.
15. Ti o si gbagbe pe, ẹsẹ le itẹ wọn fọ, tabi pe, ẹranko igbẹ le itẹ wọn fọ:
16. Kò ni ãjo si awọn ọmọ rẹ̀ bi ẹnipe nwọn kì iṣe tirẹ̀, asan ni iṣẹ rẹ̀ laibẹru:
17. Nitoripe Ọlọrun dù u li ọgbọ́n, bẹ̃ni kò si fi ipin oye fun u.
18. Nigbati o gbe ara soke, o gàn ẹṣin ati ẹlẹṣin.