Ipín si yọ fun idile awọn ọmọ Kohati: ati awọn ọmọ Aaroni alufa, ti mbẹ ninu awọn ọmọ Lefi, fi keké gbà ilu mẹtala, lati inu ẹ̀ya Juda, ati lati inu ẹ̀ya Simeoni, ati lati inu ẹ̀ya Benjamini.