Ṣugbọn ọkunrin mẹwa wà lãrin wọn ti nwọn sọ fun Iṣmaeli pe, máṣe pa wa: nitori awa ni iṣura li oko, ti alikama, ati ti ọka barli, ati ti ororo, ati oyin. Bẹ̃li o jọwọ wọn, kò si pa wọn pẹlu awọn arakunrin wọn.