10. Awọn ilu mimọ́ rẹ di aginju, Sioni dí aginju, Jerusalemu di ahoro.
11. Ile wa mimọ́ ati ologo, nibiti awọn baba wa ti nyìn ọ, li a fi iná kun: gbogbo ohun ãyo wa si ti run.
12. Iwọ o ha da ara rẹ duro nitori nkan wọnyi, Oluwa? iwọ o ha dakẹ, ki o si pọn wa loju kọja àla?