Nitorina ni iwọ ṣe kọ̀ awọn enia rẹ, ile Jakobu silẹ̀; nitoriti nwọn kún lati ìla ọ̀run wá, nwọn jẹ alafọ̀ṣẹ bi awọn ara Filistia, nwọn si nṣe inu didùn ninu awọn ọmọ alejò.