Nigbana li awọn alufa, awọn ọmọ Lefi dide, nwọn si sure fun awọn enia na: a si gbọ́ ohùn wọn, adura wọn si gòke lọ si ibugbe mimọ́ rẹ̀, ani si ọrun.