Ṣugbọn ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o wọ̀ ile Oluwa wá, bikoṣe awọn alufa, ati awọn ti nṣe iranṣẹ fun awọn ọmọ Lefi: nwọn o wọle, nitori mimọ́ ni nwọn: gbogbo awọn enia yio si ṣọ́ ẹṣọ́ Oluwa.