Ati awọn wọnyi ti a kọ orukọ wọn, dé li ọjọ Hesekiah ọba Juda, nwọn si kọlu agọ wọn, ati pẹlu awọn ara Mehuni ti a ri nibẹ, nwọn si bà wọn jẹ patapata titi di oni yi, nwọn si ngbe ipò wọn: nitori koriko mbẹ nibẹ fun agbo ẹran wọn.