Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o pa awọn oriṣa run pẹlu, emi o si jẹ ki ere wọn tán ni Nofi; kì yio si si ọmọ alade kan ni ilẹ Egipti mọ́: emi o si fi ẹ̀ru si ilẹ Egipti.