Yio si ṣe, nigbati awọn baba wọn tabi awọn arakunrin wọn ba tọ̀ wa wá lati wijọ, awa o si wi fun wọn pe, Ẹ ṣãnu wọn nitori wa: nitoriti awa kò mú aya olukuluku fun u li ogun na: bẹ̃ni ki iṣe ẹnyin li o fi wọn fun wọn; nigbana ni ẹnyin iba jẹbi.