28. Tí ó bá di àkókò ajinde, ninu àwọn mejeeje, iyawo ta ni obinrin náà yóo jẹ́, nígbà tí ó jẹ́ pé gbogbo wọn ni wọ́n ti fi ṣe aya?”
29. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣìnà, nítorí pé ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ ati agbára Ọlọrun.
30. Nítorí pé ní àkókò ajinde kò ní sí pé à ń gbé iyawo, tabi pé à ń fi ọmọ fún ọkọ; nítorí bí àwọn angẹli ti rí ní ọ̀run ni wọn yóo rí.
31. Nípa ti ajinde àwọn òkú, ẹ kò ì tíì ka ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun sọ fun yín pé,
32. ‘Èmi ni Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu.’ Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun àwọn òkú, Ọlọrun àwọn alààyè ni.”
33. Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀.
34. Nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ pé ó ti pa àwọn Sadusi lẹ́nu mọ́, wọ́n kó ara wọn jọ.
35. Ọ̀kan ninu wọn tí ó jẹ́ amòfin, bi í ní ìbéèrè kan láti fi dẹ ẹ́, pé,
36. “Olùkọ́ni, òfin wo ni ó ṣe pataki jùlọ ninu Ìwé Òfin?”
37. Jesu dá a lóhùn pé, “ ‘Fẹ́ Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo ẹ̀mí rẹ, ati ní gbogbo èrò rẹ.’
38. Èyí ni òfin tí ó ga jùlọ, òun sì ni ekinni.
39. Ekeji fi ara jọ ọ́: ‘Fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí o ti fẹ́ ara rẹ.’
40. Òfin mejeeji wọnyi ni gbogbo òfin ìyókù ati ọ̀rọ̀ inú ìwé àwọn wolii rọ̀ mọ́.”
41. Nígbà tí àwọn Farisi péjọ pọ̀, Jesu bi wọ́n pé,